ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
Yorùbá Publications (1987-2026)
Jáde
Wọlé
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Ẹ Káàbọ̀.
Ìkànnì yìí wà fún ṣíṣe ìwádìí látinú àwọn ìwé tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ní oríṣiríṣi èdè.
Bí o bá fẹ́ wa ìwé jáde, jọ̀wọ́ lọ sí jw.org.
  • Òní

Friday, November 14

Kí ẹwà yín má ṣe jẹ́ ti òde ara.—1 Pét. 3:3.

Tá a bá ń fòye báni lò, a ò ní máa dá àwọn èèyàn lẹ́jọ́. Bí àpẹẹrẹ, àwọn arábìnrin wa kan fẹ́ràn kí wọ́n máa tọ́jú tọ́tè, àwọn arábìnrin kan ò sì fẹ́ràn kí wọ́n máa ṣe bẹ́ẹ̀. Àwọn ará wa kan máa ń mutí níwọ̀nba, àwọn kan kì í sì í mu ún rárá. Gbogbo àwa Kristẹni ló máa ń wù pé ká ní ìlera tó jí pépé, àmọ́ ìtọ́jú tá a máa ń gbà yàtọ̀ síra. Tá a bá ń fipá mú àwọn ará nínú ìjọ pé kí wọ́n ṣe ohun tá a fẹ́, a lè mú àwọn ará kọsẹ̀, ó sì lè dá ìyapa sílẹ̀ láàárín wa. (1 Kọ́r. 8:9; 10:​23, 24) Bí àpẹẹrẹ, kàkà kí Jèhófà ṣòfin nípa irú aṣọ tá a máa wọ̀, ṣe ló fún wa láwọn ìlànà tí àá máa tẹ̀ lé. Ó yẹ ká máa múra lọ́nà tó yẹ àwọn òjíṣẹ́ Ọlọ́run, kó fi hàn pé à ń fòye báni lò, a mọ̀wọ̀n ara wa, a sì ní “àròjinlẹ̀.” (1 Tím. 2:​9, 10) Torí náà, tí ìmúra wa ò bá bójú mu, ó lè jẹ́ káwọn èèyàn máa wò wá láwòyanu. Bákan náà, táwọn alàgbà bá ń tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì, wọn ò ní máa gbé ìlànà tara wọn kalẹ̀ nípa irú aṣọ táwọn ará máa wọ̀ àti irú irun tó yẹ kí wọ́n ṣe. w23.07 23-24 ¶13-14

Máa Ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2025

Saturday, November 15

Ẹ tẹ́tí sí mi dáadáa, kí ẹ sì jẹ ohun tó dáa, ohun tó dọ́ṣọ̀ sì máa mú inú yín dùn gidigidi.—Àìsá. 55:2.

Jèhófà ní kí wọ́n ṣàkọsílẹ̀ ohun tó máa jẹ́ ká láyọ̀. Ìṣekúṣe táwọn tó lọ sọ́dọ̀ “òmùgọ̀ obìnrin” tó ń kígbe pè wọ́n fẹ́ ‘gbádùn’ ló jẹ́ kí wọ́n lọ síbẹ̀. Ibi tí wọ́n ti máa bá ara wọn ni “ìsàlẹ̀ Isà Òkú.” (Òwe 9:​13, 17, 18) Àmọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn tó lọ sọ́dọ̀ obìnrin tó ṣàpẹẹrẹ “ọgbọ́n tòótọ́” yàtọ̀ pátápátá! (Òwe 9:1) Torí náà, ó yẹ ká nífẹ̀ẹ́ ohun tí Jèhófà fẹ́, ká sì kórìíra àwọn ohun tí ò fẹ́. (Sm. 97:10) Yàtọ̀ síyẹn, inú wa máa ń dùn láti pe àwọn èèyàn pé káwọn náà wá jàǹfààní lára “ọgbọ́n tòótọ́.” Ṣe ló dà bí ìgbà tá à ń “ké jáde látorí àwọn ibi gíga ìlú pé: ‘Kí ẹni tó bá jẹ́ aláìmọ̀kan wọlé síbí.’” Àwa àtàwọn tó ń fetí sí wa máa jàǹfààní báyìí àti lọ́jọ́ iwájú. Ìyẹn lá jẹ́ ká “wà láàyè” títí láé bá a ṣe ń “rìn ní ọ̀nà òye nìṣó.”—Òwe 9:​3, 4, 6. w23.06 24 ¶17-18

Máa Ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2025

Sunday, November 16

Ẹni tí kì í tètè bínú sàn ju akíkanjú ọkùnrin, ẹni tó sì ń kápá ìbínú rẹ̀ sàn ju ẹni tó ṣẹ́gun ìlú.—Òwe 16:32.

Báwo ló ṣe máa ń rí lára ẹ tẹ́ni tẹ́ ẹ jọ ń ṣiṣẹ́ tàbí ọmọ ilé ìwé ẹ bá bi ẹ́ nípa ohun tó o gbà gbọ́? Ṣé ẹ̀rù máa ń bà ẹ́? Ká sòótọ́, ọ̀pọ̀ lára wa lẹ̀rù máa ń bà. Àmọ́, irú àwọn ìbéèrè bẹ́ẹ̀ lè jẹ́ ká mọ ohun tẹ́ni náà ń rò àtohun tó gbà gbọ́. Ìyẹn sì lè ṣí àǹfààní sílẹ̀ láti wàásù fún un. Nígbà míì, àwọn kan máa ń béèrè ìbéèrè torí pé wọn ò fara mọ́ ohun tá a gbà gbọ́ tàbí torí kí wọ́n lè bá wa jiyàn. Tírú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀, kò yẹ kó yà wá lẹ́nu. Ìdí ni pé wọ́n ti sọ ohun tí kì í ṣòótọ́ nípa ohun tá a gbà gbọ́ fáwọn kan. (Ìṣe 28:22) Ìdí míì ni pé “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” tí ọ̀pọ̀ èèyàn jẹ́ “kìígbọ́-kìígbà,” tí wọ́n sì “burú gan-an” là ń gbé báyìí. (2 Tím. 3:​1, 3) O lè máa ronú pé, ‘Báwo ni mo ṣe lè dáhùn lọ́nà pẹ̀lẹ́, kí n sì sọ̀rọ̀ tó tura tẹ́nì kan bá fẹ́ bá mi jiyàn nípa ohun tí mo gbà gbọ́?’ Kí ló máa ràn ẹ́ lọ́wọ́? Ìwà tútù ni. Ẹni tó bá níwà tútù kì í tètè bínú, ó máa ń kó ara ẹ̀ níjàánu tí wọ́n bá múnú bí i tàbí tí kò bá mọ ohun tó máa sọ. w23.09 14 ¶1-2

Máa Ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2025
Ẹ Káàbọ̀.
Ìkànnì yìí wà fún ṣíṣe ìwádìí látinú àwọn ìwé tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ní oríṣiríṣi èdè.
Bí o bá fẹ́ wa ìwé jáde, jọ̀wọ́ lọ sí jw.org.
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́